News
Odolaye Aremu uses the beauty of Yoruba language to eulogize ‘his beloved’ Queen Elizabeth II(must read)
Ódigbére Olólùfẹ́ Mi Aláfárá Oyin!
Ikú kọ̀ jálẹ̀, wèrè b’ara dúdú họhọ bii t’Ẹlẹ́gbára yí lóhùn ó gb’owó. Wèrè kúkúrú bìlísì yi f’àáké kọ́rí ó lóhùn ò gb’ètùtù!
A dùú síwá, a dùú sẹ́yìn, a f’ìgbà Èlíísbẹ̀ẹ̀t papa kú! Ìdí èyí lẹ́yìn wèrè o fi ri mi ń’gboro ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yí. Aájò wáìfù mi àtijọ́ ni mo ń bá kii nígbà wèrè ẹ síìkì!
Ó sì tun ti wa dájú bayi wípé ń ó tun pẹ́ díè kí n tó yọjú síta nítorí wípé ẹ̀tọ́ ni kí n ṣe opó wáìfù mi ni ìlànà àwọn baba wa. Ìfẹ́ wá kúkú dùn ṣùgbọ́n eleriibu Fílíìpù ló daarin wá rú, àti wípé ẹrú nba Gẹ̀ẹ́sì kí orí Adé ó mọ dẹ̀hìnbọ̀ wá fi Fiditi ṣe ibùgbé!
Òòka àmúdó tí mo lo gbóná buúkú! Títí tó fi dákẹ́ ni wèrè yí fi lọọfu èmi Odolaye alókó lọ́wọ́ bii ọ̀bẹ aṣoró. Baba OniWakilu tí ń dóni bii ìgbà oyinbo baa ń fi tíínkọ̀tà ṣí agolo Gẹ́ẹ́ṣà!
Gbogbo àwọn ará Gẹ̀ẹ́sì ni wọn kuku mọ wípé èmi ni bàbá Charlie! Àbíjọ temi tun le ju ti Mọṣudi Abiola! Akanni Musibau l’oókọ tí mo fún were lọ́jọ́ suna ẹ! Agiumẹnti aókọlà-aòkọlà f’ọ́mọ ló dá họ́ù-họ́ù kalẹ̀ ni wọn fi gbé wèrè yi salọ. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí òwe àwọn àgbà tó ní wípé: aya ọ̀lẹ lèèyàn ń gbà, ọmọ ọ̀lẹ – ììsì ànọ́dá matà! Ọmọ mi ti padà wálé. Ó sì ti ní kí nwa ṣe Baba Ọba. Sóó dìáfọ̀ọ́, tẹ́ẹ ba fẹẹ pemi, kẹẹ kọ́kọ́ fi “Ììsì Róyá Majẹ̀ẹ̀sìtì” síwájú oókọ mi na – tẹ́ẹ bá fẹ́ ṣ’eríibú!
Èyí jásí wípé inu ìséra ni n o wa fún ìgbà díẹ̀ ká fi ṣaáyan òkú tán. Ẹ rántí wípé: a ó sì tún pín ogún! Ogún èyí sì kúnlé-kúnà. Baba Lèmọ́mù o ní púrọ́pátì lẹgbẹ t’awon wáìfù mi àtijọ́.
A lọọfu ara wa gan-an ni! A sì dó raa wa l’ẹ́fíríwià, lórí pèpéle, lórí òkè Olúmọ, a dó raa wa lori odó iyán, a dó raa wa lori ọlọ ata- pàápàá julọ lórí kẹ̀kẹ́ẹ Ẹlẹ́mu mi àtijọ́, ṣùgbọ́n wèrè Fílíìpù onígógòńgò Ràkúnmí ló kosi wá láàrin!
Ódigbére! Ódàrìnnàkò! Ódìgbóṣe, Olólùfẹ́ Mi Èlíísbẹ̀ẹ̀t Aláfárá Oyin!
- Sports18 hours ago
Oleksandr Usyk defeats Tyson Fury to tetain heavyweight title
- Politics18 hours ago
We Will Bury PDP, Ibori’s Daughter Blows Hot
- News18 hours ago
Nigerian Emergency Agency NEMA Puts All Offices On Alert Over Fatal Stampedes
- Sports18 hours ago
CAF Made Me Believe I Won – Achraf Hakimi
- Top Stories18 hours ago
Emefiele: EFCC secures final forfeiture of 1.925 hectares of landed property linked to former CBN Governor
- News6 hours ago
NIGERIAN BREWERIES PARTNERS OZA CARNIVAL